Nahum 3:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máa wí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀? Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ṣe pé, gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Nínéfè ṣòfò: Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”