Nehemiah 1:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hanani, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi, pẹlu àwọn kan tọ̀ mí wá láti ilẹ̀ Juda, mo bá bèèrè àwọn Juu tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lọ sóko ẹrú, mo sì tún bèèrè nípa Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni Hanani, ọkan ninu awọn arakunrin mi, on ati awọn ọkunrin kan lati Juda wá sọdọ mi; mo si bi wọn lere niti awọn ara Juda ti o salà, ti o kù ninu awọn igbekùn, ati niti Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hánánì, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Júdà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jérúsálẹ́mù.