Nehemiah 1:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n sọ fún mi pé, “Inú wahala ńlá ati ìtìjú ni àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lẹ́rú wà, ati pé odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀, iná sì ti jó gbogbo ẹnu ọ̀nà rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun mi pe, Awọn iyokù, ti a fi silẹ nibẹ ninu awọn igbekùn ni igberiko, mbẹ ninu wahala nla ati ẹ̀gan; odi Jerusalemu si wó lulẹ̀, a si fi ilẹkùn rẹ̀ joná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì pada sí agbégbé ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jérúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná ṣun ẹnu ibodè rẹ̀.”