Nehemiah 1:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn tí ẹ bá pada sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa òfin mi mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀lé e, bí ẹ tilẹ̀ fọ́nká lọ sí ọ̀nà jíjìn réré, n óo ṣà yín jọ, n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti yàn pé ẹ óo ti máa sìn mí kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada si mi, ti ẹ si pa ofin mi mọ, ti ẹ si ṣe wọn, bi o tilẹ ṣepe ẹnyin ti a ti tì jade wà ni ipẹkun ọrun, emi o ko wọn jọ lati ibẹ wá, emi o si mu wọn wá si ibi ti mo ti yàn lati fi orukọ mi si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tílẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi.’