Nehemiah 10:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn akọrin, àwọn iranṣẹ tẹmpili ati àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun, àwọn iyawo wọn, àwọn ọmọ wọn ọkunrin, àwọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́njú mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn enia iyokù, awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, awọn adèna, awọn akọrin, awọn Netinimu, ati gbogbo awọn ti o ya ara wọn kuro lọdọ awọn enia ilẹ na si ofin Ọlọrun, aya wọn, awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo ẹniti o ni ìmọ ati oye;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn ènìyàn tó kù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwóo wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé