Nehemiah 10:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
wọ́n parapọ̀ pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn ọlọ́lá wọn; wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé àwọn ó máa pa òfin Ọlọrun mọ́, àwọn óo sì máa tẹ̀lé e, bí Mose iranṣẹ rẹ̀ ti fún wọn. Wọ́n óo máa ṣe gbogbo ohun tí OLUWA tíí ṣe Oluwa wọn paláṣẹ, wọn ó sì máa tẹ̀lé ìlànà ati òfin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn faramọ awọn arakunrin wọn, awọn ijoye wọn, nwọn si wọ inu èpe ati ibura, lati ma rìn ninu ofin Ọlọrun, ti a fi lelẹ nipa ọwọ Mose iranṣẹ Ọlọrun, lati kiyesi, ati lati ṣe gbogbo aṣẹ Jehofah, Oluwa wa, ati idajọ rẹ̀, ati ilana rẹ̀;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Móṣè ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfín OLÚWA, wa mọ́ dáadáa.