Nehemiah 10:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọn bá sì kó ọjà tabi oúnjẹ wá tà ní ọjọ́ ìsinmi, a kò ní rà á lọ́wọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tabi ní ọjọ́ mímọ́ kankan. A óo sì yọ̀ǹda gbogbo èso ọdún keje keje, ati gbogbo gbèsè tí eniyan bá jẹ wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn enia ilẹ na ba mu ọjà tabi ohun jijẹ wa li ọjọ isimi lati tà, awa kì yio rà a li ọwọ wọn li ọjọ isimi, tabi li ọjọ mimọ́: awa o si fi ọdun keje silẹ, ati ifi-agbara-gba gbèse.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ (ọkà) wá ní ọjọ́ ìsimi láti tà, àwa kò ní ràá ní ọwọ́ọ wọn ní ọjọ́ ìsimi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.