Nehemiah 10:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A óo máa pèsè burẹdi ìfihàn ati ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo, ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ati ti oṣù tuntun fún àwọn àsè tí wọ́n ti là sílẹ̀, ati fún gbogbo ohun mímọ́, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli kúrò, ati fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori àkara ifihàn, ati nitori ẹbọ ohun jijẹ igbagbogbo, ati nitori ẹbọ sisun igbagbogbo, ti ọjọ isimi, ti oṣù titun, ti àse ti a yàn, ati nitori ohun mimọ́, ati nitori ẹbọ ẹ̀ṣẹ lati ṣe ètutu fun Israeli, ati fun gbogbo iṣẹ ile Ọlọrun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí oúnjẹ tí ó wà lóríi tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun ṣíṣun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsimi, ti àyájọ́ oṣù tuntun àti àṣè tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.