Nehemiah 10:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ kù, ati ọrẹ wa, èso gbogbo igi, ọtí waini, ati òróró. A óo máa kó wọn tọ àwọn alufaa lọ sí gbọ̀ngàn ilé Ọlọrun wa. A óo sì máa mú ìdámẹ́wàá èso ilẹ̀ wa lọ fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n máa ń gba ìdámẹ́wàá káàkiri gbogbo ilẹ̀ wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki awa si mu akọso iyẹfun pipò wa wá, ati ọrẹ wa, ati eso oniruru igi wa, ti ọti-waini ati ti ororo fun awọn alufa, si iyẹwu ile Ọlọrun wa, ati idamẹwa ilẹ wa fun awọn ọmọ Lefi, ki awọn ọmọ Lefi ki o le ni idamẹwa ninu gbogbo ilu arọko wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ (ọkà), ti gbogbo èṣo àwọn igi àti ti wáìnì túntún wa àti ti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ọmọ Léfì ni ó ń gba ìdáwẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.