Nehemiah 10:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni yóo wà pẹlu àwọn ọmọ Lefi nígbà tí àwọn ọmọ Lefi bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóo yọ ìdámẹ́wàá gbogbo ìdámẹ́wàá tí wọ́n bá gbà lọ sí ilé Ọlọrun wa. Wọn óo kó o sinu gbọ̀ngàn ninu ilé ìpa-nǹkan-mọ́-sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alufa ọmọ Aaroni yio si wà pẹlu awọn ọmọ Lefi, nigbati awọn ọmọ Lefi yio gba idamẹwa: awọn ọmọ Lefi yio si mu idamẹwa ti idamẹwa na wá si ile Ọlọrun wa, sinu iyẹwu, sinu ile iṣura.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà tí o ti ìdílé Árónì wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Léfì yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìpamọ́ inú ilé ìṣúra.