Nehemiah 10:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Lefi yóo dá oúnjẹ, waini ati òróró jọ sinu àwọn gbọ̀ngàn, níbi tí àwọn ohun èlò tí a ti yà sí mímọ́ fún lílò ní ilé Ọlọrun wa, pẹlu àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ati àwọn olùṣọ́ tẹmpili, ati àwọn akọrin. A kò ní fi ọ̀rọ̀ ilé Ọlọrun wa falẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Lefi ni yio mu ọrẹ ọkà wá, ti ọti-waini titun, ati ororo, sinu iyẹwu, nibiti ohun èlo ibi mimọ́ gbe wà, ati awọn alufa ti nṣiṣẹ, ati awọn adèna, ati awọn akọrin: awa kì yio si kọ̀ ile Ọlọrun wa silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Léfì gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ (ọkà), wáìnì túntún àti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà-tí-ń ṣe-ìránṣẹ́-lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa rí dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”