Nehemiah 11:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù dìbò láti yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá láti lọ máa gbé Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, àwọn mẹsan-an yòókù sì ń gbé àwọn ìlú yòókù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN olori awọn enia si ngbe Jerusalemu: awọn enia iyokù si dìbo lati mu ẹnikan ninu ẹnimẹwa lati ma gbe Jerusalemu, ilu mimọ́, ati mẹsan iyokù lati ma gbe ilu miran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsinyìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù, àwọn ènìyàn tó kù sì dìbò láti mú ẹnì kọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tó kù yóò dúró sí àwọn ìlúu wọn.