Nehemiah 11:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ati àwọn arakunrin rẹ̀. Alágbára ati akọni eniyan ni wọ́n, wọ́n jẹ́ mejidinlaadoje (128). Sabidieli ọmọ Hagedolimu ni alabojuto wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn arakunrin wọn, alagbara li ogun, mejidilãdoje: ati olori wọn ni Sabdieli ọmọ ọkan ninu awọn enia nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkúnrin jẹ́ méjìdínláàdọ́je (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sábídíelì ọmọ Hágédólímù.