Nehemiah 11:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Usi ni alabojuto àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Usi yìí jẹ́ ọmọ Bani, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mika, lára àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin. Òun ni olùdarí ìsìn ninu ilé Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati alabojuto awọn ọmọ Lefi ni Jerusalemu ni Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mika. Ninu awọn ọmọ Asafu, awọn akọrin wà lori iṣẹ ile Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ní Jérúsálẹ́mù ní Húsì ọmọ Bánì, ọmọ Hásábíà, ọmọ Mátaníyà ọmọ Míkà. Húṣì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Áṣáfù tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọsìn ní ilé Ọlọ́run.