Nehemiah 11:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìletò ati àwọn pápá oko wọn, àwọn ará Juda kan ń gbé Kiriati Ariba ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, àwọn mìíràn sì ń gbé Diboni ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ati ní Jekabuseeli ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun ileto, pẹlu oko wọn, ninu awọn ọmọ Juda ngbe Kirjat-arba, ati ileto rẹ̀, ati ni Diboni, ati ileto rẹ̀, ati ni Jekabseeli, ati ileto rẹ̀,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Júdà tí ń gbé Kíríátí-Ábà, àti àwọn ìletò agbégbé e rẹ̀, ní Díbónì àti ìletò rẹ̀, ní Jékábíṣéélì.