Nehemiah 11:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ìjòyè ní àwọn agbègbè wọn ń gbé Jerusalẹmu, ṣugbọn ní àwọn ìlú Juda, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ń gbé orí ilẹ̀ rẹ̀, ní ìlú wọn, títí kan àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati àwọn ìran iranṣẹ Solomoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi si ni awọn olori igberiko ti ngbe Jerusalemu, ṣugbọn ninu ilu Juda, olukuluku ngbe inu ilẹ ìni rẹ̀ ninu ilu wọn, eyini ni: awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì ń gbé àwọn ìlúu Júdà, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìníi rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.