Nehemiah 12:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà ayé Eliaṣibu ati Joiada, Johanani ati Jadua, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ṣe àkọsílẹ̀ àwọn baálé baálé ní ìdílé baba wọn títí di àkókò ìjọba Dariusi ọba Pasia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu awọn ọmọ Lefi li ọjọ Eliaṣibu, Joiada, ati Johanani, ati Jaddua, awọn olori awọn baba: li a kọ sinu iwe pẹlu awọn alufa, titi di ijọba Dariusi ara Perṣia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olóórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìgbà ayé Élíáṣíbù, Jóíádà, Jóhánánì àti Jádúà, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dáríúsì ará a Páṣíà.