Nehemiah 12:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n jẹ́ aṣiwaju ninu àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Haṣabaya, Ṣerebaya, ati Joṣua ọmọ Kadimieli pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró kọjú sí ara wọn, àwọn ìhà mejeeji yin Ọlọrun lógo wọ́n sì dúpẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi, eniyan Ọlọrun fi lélẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn olori awọn ọmọ Lefi si ni Haṣabiah, Ṣerebiah, ati Jeṣua ọmọ Kadmieli, pẹlu awọn arakunrin wọn kọju si ara wọn, lati yìn ati lati dupẹ, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi enia Ọlọrun, li ẹgbẹgbẹ ẹṣọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn olóórí àwọn ọmọ Léfì ni Háṣábáyà, Ṣérébáyà, Jéṣúà ọmọ Kádímíélì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojúu wọn láti ròyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run.