Nehemiah 12:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ odi ìlú náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Lefi jọ láti gbogbo ibi tí wọ́n wà, wọ́n kó wọn wá sí Jerusalẹmu, láti wá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ náà pẹlu orin ọpẹ́ ati kimbali ati hapu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nigba yiya odi Jerusalemu si mimọ́, nwọn wá awọn ọmọ Lefi kiri ninu gbogbo ibugbe wọn, lati mu wọn wá si Jerusalemu lati fi ayọ̀ ṣe iyà si mimọ́ na pẹlu idupẹ ati orin, pẹlu simbali, psalteri, ati pẹlu dùru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jérúsálẹ́mù a mú ọmọ Léfì jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jérúsálẹ́mù láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin síḿbálì, háápù àti dùùrù.