Nehemiah 12:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bá kó àwọn ìjòyè Juda lọ sórí odi náà, mo sì yan ọ̀wọ́ meji pataki tí wọ́n ṣe ìdúpẹ́ tí wọ́n sì tò kọjá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Àwọn kan tò lọ ní apá ọ̀tún odi náà lọ sí Ẹnubodè Ààtàn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo mu awọn ijoye Juda wá si ori odi, mo si yàn ẹgbẹ nla meji, ninu awọn ti ndupẹ, ẹgbẹ kan lọ si apa ọtun li ori odi, siha ẹnu-bode àtan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì tún yan àwọn olórí Júdà láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn.