Nehemiah 12:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ati àwọn arakunrin rẹ̀ wọnyi: Ṣemaaya, Asareli ati Milalai, Gilalai, Maai ati Netaneli, Juda, ati Hanani, pẹlu àwọn ohun èlò orin Dafidi eniyan Ọlọ́run. Ẹsira, akọ̀wé, ni ó ṣáájú, àwọn eniyan sì tẹ̀lé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn arakunrin rẹ̀, Ṣemaiah, ati Asaraeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneeli, ati Juda, Hanani, pẹlu ohun èlo orin Dafidi, enia Ọlọrun, ati Esra akọwe niwaju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀—Ṣémáyà, Áṣárélì, Míláláì, gíláláì, Mááì, Nétanélì, Júdà àti Hánánì—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run. Éṣírà akọ̀wé ni ó sáájúu wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́.