Nehemiah 12:44 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, wọ́n yan àwọn kan láti mójútó àwọn ilé ìṣúra, ati ọrẹ tí àwọn eniyan dájọ, àwọn èso àkọ́so, ati ìdámẹ́wàá, àwọn tí wọ́n yàn ni wọ́n ń mójútó pípín ẹ̀tọ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé òfin. Inú àwọn ará ilẹ̀ Juda dùn pupọ sí àwọn alufaa ati sí àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akoko na li a si yàn awọn kan ṣe olori yara iṣura, fun ọrẹ-ẹbọ, fun akọso, ati fun idamẹwa, lati ma ko ipin ti a yàn jọ lati oko ilu wọnni wá, ti ofin fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: nitoriti Juda yọ̀ fun awọn ọmọ Lefi ti o duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìkó ẹrù fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìkó nǹkan sí ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, nítorí inú un àwọn ará a Júdà yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ, Léfì tó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ.