Nehemiah 13:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò náà mo rí àwọn ọmọ Juda tí wọn ń fún ọtí waini ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń kó ìtí ọkà jọ, tí wọn ń dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí wọn sì ń gbé waini, ati èso girepu, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ ati oríṣìíríṣìí ẹrù wúwo wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi, mo bá kìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó yẹ kí wọ́n máa ta oúnjẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ wọnni ni mo ri awọn kan ti nfunti ni Juda li ọjọ isimi, awọn ti nmu iti ọka wale, ti ndi ẹrù rù kẹtẹkẹtẹ; ti ọti-waini, pẹlu eso àjara, ati eso ọ̀pọtọ, ati gbogbo oniruru ẹrù ti nwọn nmu wá si Jerusalemu li ọjọ isimi: mo si jẹri gbè wọn li ọjọ ti nwọn ntà ohun jijẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Júdà tí wọ́n ń fún wáìnì ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé oríi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà.