Nehemiah 13:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọkunrin kan láti Tire pàápàá tí wọn ń gbé ààrin ìlú náà mú ẹja wá ati oríṣìíríṣìí àwọn nǹkan títà, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn eniyan Juda ati ni Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Tire ngbe ibẹ pẹlu, ti nwọn mu ẹja, ati oniruru ohun èlo wá, nwọn si ntà li ọjọ isimi fun awọn ọmọ Juda, ati ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Tírè ti ń gbé nínú un Jérúsálẹ́mù ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún àwọn ọmọ Júdà.