Nehemiah 13:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Irú nǹkan burúkú yìí kọ́ ni àwọn baba yín pàápàá ṣe tí Ọlọrun fi mú kí ibi bá àwa ati ìlú yìí? Sibẹ, ẹ tún ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi, ẹ̀ ń fa ìrúnú Ọlọrun sórí Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ha kọ́ awọn baba nyin ṣe, Ọlọrun kò ha mu ki gbogbo ibi yi wá sori wa, ati sori ilu yi? ṣugbọn ẹnyin mu ibinu ti o pọ̀ju wá sori Israeli nipa biba ọjọ isimi jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé àwọn baba ńlá yín kòha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá oríi wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú ṣókè síi sórí Ísírẹ́lì nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.”