Nehemiah 13:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣú ní àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu kí ó tó di ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ìlẹ̀kùn, ati pé wọn kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀ títí tí ọjọ́ ìsinmi yóo fi rékọjá. Mo yan díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ mi sí àwọn ẹnubodè náà, kí wọ́n má baà kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati ẹnu-bode Jerusalemu bẹ̀rẹ si iṣu okunkun ṣaju ọjọ isimi, mo paṣẹ pe, ki a tì ilẹkun, ki ẹnikẹni má ṣi i titi di ẹhin ọjọ isimi, ninu awọn ọmọkunrin mi ni mo fi si ẹnu-bode, ki a má ba mu ẹrù wọle wá li ọjọ isimi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jérúsálẹ́mù, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì sí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ẹ̀ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.