Nehemiah 13:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí pé wọn kò gbé oúnjẹ ati omi lọ pàdé àwọn ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu lọ́wẹ̀ láti máa gbé àwọn ọmọ Israẹli ṣépè, ṣugbọn Ọlọrun wa yí èpè náà pada sí ìre fún Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti nwọn kò fi onjẹ ati omi ko awọn ọmọ Israeli lọna, ṣugbọn nwọn bẹ̀ Balaamu lọwẹ si wọn, lati fi wọn gegun: ṣugbọn Ọlọrun wa sọ egun na di ibukun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Bálámù ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn-ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún).