Nehemiah 13:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n wá láti ṣọ́ àwọn ẹnubodè, kí wọn lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Ranti eléyìí fún rere mi, Ọlọrun mi, kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ya ara wọn si mimọ, ki nwọn si wa ṣọ ẹnu-bode lati pa ọjọ isimi mọ. Ranti mi Ọlọrun mi nitori eyi pẹlu, ki o si da mi si gẹgẹ bi ọ̀pọ ãnu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Tún rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ẹ̀ rẹ.