Nehemiah 13:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bínú sí wọn mo sì gbé wọn ṣépè, mo na àwọn mìíràn, mo sì fa irun wọn tu. Mo sì mú wọn búra ní orúkọ Ọlọrun wí pé: “Ẹ kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọ wọn, tabi kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín tabi kí ẹ̀yin pàápàá fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ba wọn jà, mo gàn wọn, mo lù ninu wọn, mo tu irun wọn, mo mu wọn fi Ọlọrun bura pe, Ẹnyin kì yio fi ọmọbinrin nyin fun ọmọkunrin nwọn, tabi ọmọbinrin nwọn fun ọmọkunrin nyin tabi fun ara nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo bá wọn wí mo sì gégùn-ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú un wọn mo sì fa irun oríi wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkáara yín.