Nehemiah 13:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣebí Solomoni ọba pàápàá dẹ́ṣẹ̀ nítorí ó fẹ́ irú àwọn obinrin bẹ́ẹ̀. Kò sí ọba tí ó dàbí rẹ̀ láàrin àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, Ọlọrun sì fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọrun sì fi jọba lórí gbogbo Israẹli, sibẹsibẹ, àwọn obinrin àjèjì ni wọ́n mú un dẹ́ṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni ọba Israeli kò ha dẹṣẹ nipa nkan wọnyi? Bẹ̃ni li ãrin orilẹ-ède pupọ, kò si ọba kan bi on ti Ọlọrun rẹ̀ fẹràn; Ọlọrun si fi jẹ ọba li ori gbogbo Israeli, bẹ̃ni on li awọn àjeji obinrin mu ki o ṣẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kìí ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Sólómónì fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrin àwọn orìlẹ̀ èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ féràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lóríi gbogbo Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjòjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀.