Nehemiah 13:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó ṣètò yàrá ńlá kan fún Tobaya níbi tí wọ́n ń tọ́jú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ sí, ati turari, àwọn ohun èlò ìrúbọ, pẹlu ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn akọrin, ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, pẹlu àwọn ohun tí wọ́n dá jọ fún àwọn alufaa gẹ́gẹ́ bí òfin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ti pèse iyẹwu nla kan fun u, nibiti nwọn ima fi ẹbọ ohun jijẹ, turari, ati ohun èlo, ati idamẹwa agbado, ọti-waini titun, ati ororo si nigba atijọ, eyi ti a pa li aṣẹ lati fi fun awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna: ati ẹbọ ọrẹ awọn alufa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹ́ḿpìlì àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lúu gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.