Nehemiah 13:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N kò sí ní Jerusalẹmu ní gbogbo àkókò tí nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀, nítorí pé ní ọdún kejilelọgbọn ìjọba Atasasesi, ọba Babiloni, ni mo ti pada tọ ọba lọ. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, mo gba ààyè lọ́wọ́ ọba,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ni gbogbo àkoko yi, emi kò si ni Jerusalemu: nitori li ọdun kejilelọgbọn ti Artasasta ọba Babiloni, mo wá si ọdọ ọba, ati li opin ọjọ wọnni, mo gba àye lati ọdọ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jérúsálẹ́mù, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Aritaṣéṣéṣì ọba Bábílónì ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀.