Nehemiah 13:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá pàṣẹ pé kí wọ́n tún yàrá náà ṣe kí ó mọ́, ẹ̀yìn náà ni mo wá kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun pada ati ọrẹ ẹbọ ohun sísun ati turari.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo paṣẹ, nwọn si wẹ̀ iyẹwu na mọ: si ibẹ ni mo si tun mu ohun èlo ile Ọlọrun wá, pẹlu ẹbọ ohun jijẹ ati turari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí.