Nehemiah 2:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní oṣù Nisani, ní ogún ọdún tí Atasasesi ọba gorí oyè, mo gbé ọtí waini tí ó wà níwájú rẹ̀ fún un. N kò fajúro níwájú rẹ̀ rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li oṣu Nisani, li ogún ọdun Artasasta ọba, ọti-waini wà niwaju rẹ̀: mo si gbe ọti-waini na, mo si fi fun ọba. Emi kò si ti ifajuro niwaju rẹ̀ rí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní oṣù Níṣánì (oṣù kẹrin) ní ogún ọdún ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún-un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, Ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájúu rẹ̀.