Nehemiah 2:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si dide li oru, emi ati ọkunrin diẹ pẹlu mi: emi kò si sọ fun enia kan ohun ti Ọlọrun mi fi si mi li ọkàn lati ṣe ni Jerusalemu: bẹni kò si ẹranko kan pẹlu mi, bikoṣe ẹranko ti mo gùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnikankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jérúsálẹ́mù. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lúu mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.