Nehemiah 2:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ìjòyè náà kò sì mọ ibi tí mo lọ tabi ohun tí mo lọ ṣe, n kò sì tíì sọ nǹkankan fún àwọn Juu, ẹlẹgbẹ́ mi: àwọn alufaa, ati àwọn ọlọ́lá, tabi àwọn ìjòyè ati àwọn yòókù tí wọn yóo jọ ṣe iṣẹ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ijoye kò si mọ̀ ibi ti mo lọ, tabi ohun ti mo ṣe; emi kò ti isọ fun awọn ara Juda tabi fun awọn alufa, tabi fun awọn alagba, tabi fun awọn ijoye; tabi fun awọn iyokù ti o ṣe iṣẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.