Nehemiah 2:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo sọ fún wọn nípa bí Ọlọrun ṣe lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi ati nípa ọ̀rọ̀ tí ọba bá mi sọ. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á múra kí á sì kọ́ ọ.” Wọ́n sì gbáradì láti ṣe iṣẹ́ rere náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo si sọ fun wọn niti ọwọ Ọlọrun mi, ti o dara li ara mi; ati ọ̀rọ ọba ti o ba mi sọ. Nwọn si wipe, Jẹ ki a dide, ki a si mọ odi! Bẹni nwọn gba ara wọn ni iyanju fun iṣẹ rere yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi. Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí.