Nehemiah 2:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni ati Geṣemu ará Arabia gbọ́, wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń pẹ̀gàn wa pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ̀ ń dìtẹ̀ mọ́ ọba ni?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati Sanballati ara Horoni, ati Tobiah iranṣẹ, ara Ammoni, ati Gesẹmu, ara Arabia, gbọ́, nwọn fi wa rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wa, nwọn si wipe, Kini ẹnyin nṣe yi? ẹnyin o ha ṣọ̀tẹ si ọba bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì ará a Hórónì, Tòbáyà ara olóyè Ámónì àti Géṣémù ará a Arábíyà gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?”