Nehemiah 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀rù bà mí pupọ. Mo bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ẹ̀mí ọba gùn! Báwo ni ojú mi kò ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, ti di ahoro, tí iná sì ti jó àwọn ẹnubodè rẹ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun ọba pe, Ki ọba ki o pẹ: ẽṣe ti oju mi kì yio fi faro, nigbati ilu, ile iboji awọn baba mi dahoro, ti a si fi iná sun ilẹkun rẹ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! È é ṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?”