Nehemiah 2:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá sọ fún ọba pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn, tí èmi iranṣẹ rẹ bá sì rí ojurere rẹ, rán mi lọ sí Juda, ní ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, kí n lọ tún ìlú náà kọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun ọba pe, Bi o ba wù ọba, ati bi iranṣẹ rẹ ba ri ojurere lọdọ rẹ, ki iwọ le rán mi lọ si Juda, si ilu iboji awọn baba mi, ki emi ki o ba le kọ́ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Júdà ní bi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.”