Nehemiah 2:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ayaba wà ní ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “O óo lò tó ọjọ́ mélòó lọ́hùn-ún? Ìgbà wo ni o sì fẹ́ pada?” Inú ọba dùn láti rán mi lọ, èmi náà sì dá ìgbà fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun mi pe, (ayaba si joko tì i) ajo rẹ yio ti pẹ to? nigbawo ni iwọ o si pada? Bẹli o wù ọba lati rán mi; mo si dá àkoko kan fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan.