Nehemiah 3:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hanuni ati àwọn tí ń gbé Sanoa tún Ẹnubodè Àfonífojì ṣe, wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀. Wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, wọ́n sì tún odi rẹ̀ kọ́ ní ìwọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), sí Ẹnubodè Ààtàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hanuni pẹlu awọn ará Sanoa si tun ẹnu-bode afonifoji ṣe; nwọn kọ́ ọ, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itikùn rẹ̀, ati ẹgbẹrun igbọnwọ odi titi de ẹnu-bode ãtàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ibodè Àfonífojì ni Hánúnì àti àwọn ará Ṣánóà tún mọ. Wọ́n tún-un kọ́ wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ide rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún-ún kan ìgbọ̀nwọ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn.