Nehemiah 3:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Malikija ọmọ Rekabu, aláṣẹ agbègbè Beti Hakikeremu, ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Ààtàn, ó tún un kọ́, ó so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ó sì ṣe àwọn ìdábùú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnu-bode ãtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, ijòye apa kan Bet-hakkeremu tun ṣe; o kọ́ ọ, o gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itìkun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnu ìbodè Ààtàn ni Málíkíjà ọmọ Rákábù, alákóṣo agbégbé Bẹti-Hákérémù tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìde rẹ̀ sí ààyè wọn.