Nehemiah 3:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn rẹ̀ Malikija, ọ̀kan ninu àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn iranṣẹ tẹmpili ati ilé àwọn oníṣòwò, níbi tí ó kọjú sí Ẹnu Ọ̀nà Mifikadi, ati títí dé yàrá òkè orígun odi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin rẹ̀ ni Malkiah ọmọ alagbẹdẹ wura tun ṣe, titi de ile awọn Netinimu ati ti awọn oniṣòwo, li ọkánkán ẹnu bode Mifkadi ati yàra òke igun-odi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Mákíjà, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀;