Nehemiah 3:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn wọn ni Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn. Lẹ́yìn wọn, Meṣulamu ọmọ Berekaya, ọmọ Meṣesabeli náà ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn. Lẹ́yìn wọn ni Sadoku, ọmọ Baana náà ṣe àtúnṣe abala tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọwọkọwọ wọn ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi, tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Sadoku, ọmọ Baana tun ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákóṣì tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Mésúlámù ọmọ Bérékíà, ọmọ Méṣéábélì tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ. Bákan ńaà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣádókù ọmọ Báánà náà tún odi mọ.