Nehemiah 3:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joiada, ọmọ Pasea, ati Meṣulamu, ọmọ Besodeaya, ni wọ́n ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Àtijọ́. Wọ́n ṣe ẹnu ọ̀nà, wọ́n ṣe àwọn ìlẹ̀kùn, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoida, ọmọ Pasea, ati Meṣullamu, ọmọ Besodiah, si tun ẹnu-bode atijọ ṣe, nwọn tẹ̀ igi idabu rẹ̀, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, ati àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóádà ọmọ Páṣéà àti Mésúlámù ọmọ Béṣódáyà ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.