Nehemiah 3:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn wọn ni àwọn Melataya, ará Gibeoni, Jadoni, ará Meronoti, ati àwọn ará Gibeoni ati àwọn ará Misipa tí wọ́n wà ní abẹ́ ìjọba Ìkọjá Odò ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọwọkọwọ wọn ni Melatiah, ará Gibeoni, tun ṣe, ati Jadoni, ara Merono, awọn ọkunrin ti Gibeoni, ati ti Mispa, ti o jẹ ti itẹ bãlẹ̀ apa ihin odò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gíbíónì àti Mísípà: Mélátíà ti Gíbíónì àti Jádónì ti Mérónótì; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Éfúrétè.