Nehemiah 3:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Usieli ọmọ Hariaya alágbẹ̀dẹ wúrà ló ṣiṣẹ́ tẹ̀lé wọn. Lẹ́yìn wọn ni Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn onítùràrí ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀, wọ́n sì ṣe é dé ibi Odi Gbígbòòrò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Ussieli ọmọ Harhiah, alagbẹdẹ wura tun ṣe; ati lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hananiah ọmọ alapolu, tun ṣe; nwọn si ti fi Jerusalemu silẹ̀ titi de odi gbigbõro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Úsíélì ọmọ Hariháyà, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananíyà, ọ̀kan lára awọn tí ó ń ṣe tùràrí, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jérúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò títí dé Odi Gbígbòòrò.