Nehemiah 4:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà mo fi àwọn eniyan ṣọ́ gbogbo ibi tí odi ìlú bá ti gba ibi tí ilẹ̀ ti dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, mo yan olukuluku ní ìdílé ìdílé, wọ́n ń ṣọ́ odi ní agbègbè wọn pẹlu idà, ọ̀kọ̀, ati ọrun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni mo yàn awọn enia si ibi ti o rẹlẹ lẹhin odi, ati si ibi gbangba, mo tilẹ yàn awọn enia gẹgẹ bi idile wọn, pẹlu idà wọn, ọ̀kọ wọn, ati ọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílée wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn.