Nehemiah 4:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ lójú àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn Juu aláìlera wọnyi ń ṣé? Ṣé wọn yóo tún ìlú wọn kọ́ ni? Ṣé wọn yóo tún máa rúbọ ni? Ṣé ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n fẹ́ parí rẹ̀ ni? Ṣé wọn yóo lè yọ àwọn òkúta kúrò ninu àlàpà tí wọ́n wà, kí wọn sì fi òkúta tí ó ti jóná gbẹ́ òkúta ìkọ́lé?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si sọ niwaju awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ-ogun Samaria pe, Kini awọn alailera Juda wọnyi nṣe yi? nwọn o ha dá wà fun ara wọn bi? nwọn o ha rubọ? nwọn o ha ṣe aṣepari ni ijọkan? nwọn o ha mu okuta ti a ti sun lati inu okìti sọji?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ ogun Ṣamáríà pé, “Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí? Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni? Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni? Ṣé wọn yóò paríi rẹ̀ lóòjọ́ ni bí? Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti ṣun láti inú òkítì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà yẹn?”